AIGBAGBO, BILA! TEMI L'OLUWA
Yoruba Hymnal
๐ถ๐ถ๐ถ๐ถ๐ถ๐ต๐ต
1. Aigbagbo, bila! Temi l'Oluwa
On o si dide fun igbala mi Ki nsa ma gbadura, On o se'ranwo 'Gba Krist' wa lodo mi, ifoiya ko si
2. B'ona mi basu, On lo sa nto mi Ki nsagboran sa, On o si pese
Bi iranlowo eda gbogbo saki Oro t'enu Re so y'o bori dandan
3. Ife t'o nfihan ko je ki nro pe Y'o fi mi sile ninu wahala Iranwo ti mo si nri lojojumo O nki mi laiya pe emi o la ja
4. Emi o se kun 'tori iponju Tabi irora? O ti so tele! Mo m'oro Re p'awon ajogun 'gbala Nwon ko le s'aikoja larin wahala
5. Eda ko le so kikoro ago T'Olugbala mu k'elese le ye Aiye Re tile buru ju temi lo Jesu ha le jiya, k'emi si ma sa!
6. Nje b'ohun gbogbo ti nsise ire Fun awon t'o duro de Oluwa B'oni tile koro, sa ko ni pe mo 'Gbana orin 'segun yio ti dun to
Comments
Post a Comment