Ko su wa lati ma ko orin ti igbani (Hymn)
1. Ko su wa lati ma ko orin ti igbani
Ogo f’olorun Aleluya
A le fi igbagbo korin na s’oke kikan
Ogo f’olorun, Aleluya!
Omo olorun ni eto lati ma bu s’ayo
Pe ona yi nye wa si,
Okan wa ns’aferi Re
Nigb’o se a o de afin Oba wa ologo,
Ogo f’olorun, Aleluya!
2. Awa mbe n’nu ibu ife t’o ra wa pada,
ogo f’olorun Aleluya!
Awa y’o fi iye goke lo s’oke orun
Ogo f’olorun, Aleluya!
3. Awa nlo si afin kan ti a fi wura ko,
ogo f’olorun Aleluya!
Nibiti a ori Oba ogo n’nu ewa Re
Ogo f’olorun, Aleluya!
4. Nibe ao korin titun t’anu t’o da wa nde
Ogo f’olorun Aleluya!
Nibe awon ayanfe yo korin ‚yin ti Krist;
Ogo f’olorun, Aleluya!. Amin
Comments
Post a Comment