Toju iwa re ore mi
Toju Iwa re, ore mi!
Ola a ma si lo n'ile eni,
Ewa a si ma si l'ara enia,
Olowo oni 'ndi olosi b'o d'ola
Okun l'ola, okun nigbi oro
Gbogbo won l'o 'nsi lo nile eni
Sugbon Iwa ni 'mba ni de Saree
Owo ko je nkan fun 'ni
Iwa l'ewa l'omo enia
Bi o l'owo bi o ko ni wa nko
Tani je f'inu tan o ba s'ohun rere?
Tabi bi o si se obirin rogbodo,
Bi o ba jina si 'wa ti eda 'nfe
Tani je fi a s'ile bi aya?
Tabi bi o je onijibiti enia
Bi a tile mo iwe amodaju
Tani je gbe'se aje fun o se?
Toju Iwa re, ore mi,
Iwa ki si, eko d'egbe,
Gbogbo aiye ni 'nfe 'ni t'o je rere.
Comments
Post a Comment