Ise ni oogun Ise - J F Odunjo
Mura si ise ore mi
Ise ni afi ndeni giga
Bi ako ba reni fehinti
Bi ole la a ri
Bi a ko ba reni gbekele
A tera mose eni
Iya re le lowo lowo
Baba re si le leshin le kan
Bi o ba gboju le won
O te tan ni mo so fun o
Ohun ti a ko ba jiya fun
Se kii le tojo
Ohun ti a ba fara sise fun
Ni npe lowo eni
Apa lara
Igunpa ni iye kan
Bi aiye ba nfe o loni
Ti o balowo lowo
Won a ma fe o lola
Jeki o wa ni ipo atata
Aiye a ma ye o si terin-terin
Jeki o deni rago
Ko o ri bi aiye ti nyinmu si o
Eko si tun seni doga
Mura ki o ko dara-dara
Iya nbo fomo ti ko gbon
Ekun mbe fomo ti o nsa kiri
Ma fowuro sere ore mi
Mura si ise ojo nlo.
© JF Odunjo
Comments
Post a Comment